ẸGBA MỌ LISABI
Ẹ̀gbá ‘mọ Lísàbí
Agbòǹgbò àkàlà
Ọmọ erin j’ogún ọlá
Ọmọ ṣí ‘lẹ̀kùn pa ‘lẹ̀kùn dé
Aridi ògo lójú Ogun
Baba t’ẹ̀yin ni wọ́n ròyìn ogun bààrà f’ágbe
Ẹ̀gbá, ọmọ adúró gbẹrú, má dúró gbẹ̀kọ
Ẹrú ní nsini, ẹ̀kọ kìí sìn ’yàn
Kò s’óhun tí wọ́n ǹṣe ní mọ́kà
T’ẹ́yin kìí ṣe l’Ẹ̀gbá Aláké yín
Wọ́n ń munmi sẹ́mí-sẹ́mí ní Mọ́kà
Ẹ̀yin náà n munmi Odò Ògùn l’Ẹ̀gbá Aláké
Wọ́n ń g’Àràfá ní Mọ́kà Ẹ̀yin n g’orí Olúmo l’Ẹ̀gbá ti yín
Wọ́n bí yin L’Áké
Ẹ gbó lẹ́nu bí jeje
Wọ́n bí yin ní Gbàgùrá
Ẹ gbó l’óhùn bí ọ̀jẹ̀.
Ọba òkè bá wa dá ìlú Ẹ̀gbá sí
Comments
Post a Comment