Posts

Showing posts from November, 2024

ẸGBA MỌ LISABI

Ẹ̀gbá ‘mọ Lísàbí Agbòǹgbò àkàlà Ọmọ erin j’ogún ọlá Ọmọ ṣí ‘lẹ̀kùn pa ‘lẹ̀kùn dé Aridi ògo lójú Ogun Baba t’ẹ̀yin ni wọ́n ròyìn ogun bààrà f’ágbe Ẹ̀gbá, ọmọ adúró gbẹrú, má dúró gbẹ̀kọ Ẹrú ní nsini, ẹ̀kọ kìí sìn ’yàn Kò s’óhun tí wọ́n ǹṣe ní mọ́kà T’ẹ́yin kìí ṣe l’Ẹ̀gbá Aláké yín Wọ́n ń munmi sẹ́mí-sẹ́mí ní Mọ́kà Ẹ̀yin náà n munmi Odò Ògùn l’Ẹ̀gbá Aláké Wọ́n ń g’Àràfá ní Mọ́kà Ẹ̀yin n g’orí Olúmo l’Ẹ̀gbá ti yín Wọ́n bí yin L’Áké Ẹ gbó lẹ́nu bí jeje Wọ́n bí yin ní Gbàgùrá Ẹ gbó l’óhùn bí ọ̀jẹ̀. Ọba òkè bá wa dá ìlú Ẹ̀gbá sí